Samuẹli Keji 13:31-39 BIBELI MIMỌ (BM)

31. Ọba dìde, ó fa aṣọ rẹ̀ ya láti fi ìbànújẹ́ rẹ̀ hàn, ó sì sùn sórí ilẹ̀ lásán, àwọn iranṣẹ rẹ̀ tí wọ́n wà pẹlu rẹ̀ fa aṣọ tiwọn náà ya.

32. Ṣugbọn Jonadabu, ọmọ Ṣimea, arakunrin Dafidi, wí fún ọba pé, “Kabiyesi, ẹnikẹ́ni kò pa gbogbo àwọn ọmọ rẹ. Amnoni nìkan ni Absalomu pàṣẹ pé kí wọ́n pa. Láti ìgbà tí Amnoni ti fi ipá bá Tamari, arabinrin rẹ̀ lòpọ̀, ni ó ti pinnu láti ṣe ohun tí ó ṣe yìí.

33. Nítorí náà, kí oluwa mi má gba ìròyìn tí wọ́n mú wá gbọ́, pé gbogbo àwọn ọmọ rẹ̀ ni wọ́n ti kú. Amnoni nìkan ni wọ́n pa.”

34. Absalomu sá lọ ní àkókò yìí.Kò pẹ́ rárá, lẹ́yìn náà, ọmọ ogun tí ń ṣọ́ ọ̀nà tí ó wọ ìlú rí ogunlọ́gọ̀ eniyan, wọ́n ń bọ̀ láti ọ̀nà Horonaimu, lẹ́bàá òkè.

35. Jonadabu bá sọ fún ọba pé, “Àwọn ọmọ oluwa mi ni wọ́n ń bọ̀ yìí, gẹ́gẹ́ bí mo ti wí.”

36. Ó fẹ́rẹ̀ má tíì dákẹ́ ọ̀rọ̀ tí ó ń sọ, tí àwọn ọmọ Dafidi fi wọlé, tí wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí sọkún, Dafidi ati àwọn iranṣẹ rẹ̀ náà sì sọkún tẹ̀dùntẹ̀dùn.

37. Ṣugbọn Absalomu sá lọ sọ́dọ̀ Talimai, ọmọ Amihudu, ọba Geṣuri, Dafidi sì ń ṣọ̀fọ̀ ọmọ rẹ̀ lojoojumọ.

38. Absalomu wà ní Geṣuri níbi tí ó sá lọ fún ọdún mẹta.

39. Nígbà tí ó yá tí Dafidi gbé ìbànújẹ́ ikú Amnoni ọmọ rẹ̀ kúrò lára, ọkàn Absalomu ọmọ rẹ̀ bẹ̀rẹ̀ sí fà á.

Samuẹli Keji 13