9. Kí ló dé tí o fi kẹ́gàn ọ̀rọ̀ OLUWA, tí o sì ṣe nǹkan burúkú yìí níwájú rẹ̀. Ìwọ ni o fi Uraya fún ogun pa; tí o jẹ́ kí àwọn Amoni pa á. Lẹ́yìn náà, o gba aya rẹ̀.
10. Nítorí náà, ogun kò ní kúrò ní ìdílé rẹ títí lae; nítorí pé o ti kẹ́gàn mi, o sì ti gba aya Uraya.
11. Èmi OLUWA ni mo sọ bẹ́ẹ̀. Wò ó! N óo jẹ́ kí ẹnìkan ninu ìdílé rẹ ṣe ibi sí ọ. Ojú rẹ ni yóo ṣe tí n óo fi fi àwọn aya rẹ fún ẹlòmíràn, tí yóo sì máa bá wọn lòpọ̀ ní ọ̀sán gangan.
12. Níkọ̀kọ̀ ni o dá ẹ̀ṣẹ̀ yìí, ṣugbọn níwájú gbogbo Israẹli, ní ọ̀sán gangan, ni n óo ṣe ohun tí mò ń sọ yìí.’ ”
13. Dafidi bá dáhùn pé, “Mo ti ṣẹ̀ sí OLUWA.”Natani dá a lóhùn pé, “OLUWA ti dáríjì ọ́, o kò sì ní kú.
14. Ṣugbọn nítorí pé ohun tí o ṣe yìí jẹ́ àfojúdi sí OLUWA, ọmọ tí ó bí fún ọ yóo kú.”
15. Natani bá lọ sí ilé rẹ̀.OLUWA fi àìsàn ṣe ọmọ tí aya Uraya bí fún Dafidi.
16. Dafidi bá ń gbadura sí Ọlọrun pé kí ara ọmọ náà lè yá, ó ń gbààwẹ̀, ó sì ń sùn lórí ilẹ̀ lásán ní alaalẹ́.
17. Àwọn àgbààgbà tí wọ́n wà ninu ilé rẹ̀ rọ̀ ọ́, pé kí ó dìde nílẹ̀, ṣugbọn ó kọ̀, kò sì bá wọn jẹ nǹkankan.
18. Ní ọjọ́ keje, ọmọ náà kú, ẹ̀rù sì ba àwọn iranṣẹ Dafidi láti sọ fún un pé ọmọ ti kú. Wọ́n ní, “Ìgbà tí ọmọ yìí wà láàyè, a bá Dafidi sọ̀rọ̀, kò dá wa lóhùn. Báwo ni a ṣe fẹ́ sọ fún un pé ọmọ ti kú? Ó lè pa ara rẹ̀ lára.”