6. Ó sì níláti san ìlọ́po mẹrin ọmọ aguntan tí ó gbà pada, nítorí nǹkan burúkú tí ó ṣe, ati nítorí pé kò ní ojú àánú.
7. Natani bá dá Dafidi lóhùn pé, “Ìwọ gan-an ni ẹni náà. Ohun tí OLUWA Ọlọrun Israẹli sì ní kí n wí fún ọ nìyí; ó ní, ‘Mo fi ọ́ jọba lórí Israẹli, mo sì gbà ọ́ kúrò lọ́wọ́ Saulu.
8. Mo fún ọ ní ilé oluwa rẹ ati àwọn aya rẹ̀. Mo fi ọ́ jọba lórí Israẹli ati Juda. Ati pé, bí èyí kò bá tó ọ, ǹ bá fún ọ ní ìlọ́po meji rẹ̀.
9. Kí ló dé tí o fi kẹ́gàn ọ̀rọ̀ OLUWA, tí o sì ṣe nǹkan burúkú yìí níwájú rẹ̀. Ìwọ ni o fi Uraya fún ogun pa; tí o jẹ́ kí àwọn Amoni pa á. Lẹ́yìn náà, o gba aya rẹ̀.
10. Nítorí náà, ogun kò ní kúrò ní ìdílé rẹ títí lae; nítorí pé o ti kẹ́gàn mi, o sì ti gba aya Uraya.
11. Èmi OLUWA ni mo sọ bẹ́ẹ̀. Wò ó! N óo jẹ́ kí ẹnìkan ninu ìdílé rẹ ṣe ibi sí ọ. Ojú rẹ ni yóo ṣe tí n óo fi fi àwọn aya rẹ fún ẹlòmíràn, tí yóo sì máa bá wọn lòpọ̀ ní ọ̀sán gangan.
12. Níkọ̀kọ̀ ni o dá ẹ̀ṣẹ̀ yìí, ṣugbọn níwájú gbogbo Israẹli, ní ọ̀sán gangan, ni n óo ṣe ohun tí mò ń sọ yìí.’ ”
13. Dafidi bá dáhùn pé, “Mo ti ṣẹ̀ sí OLUWA.”Natani dá a lóhùn pé, “OLUWA ti dáríjì ọ́, o kò sì ní kú.
14. Ṣugbọn nítorí pé ohun tí o ṣe yìí jẹ́ àfojúdi sí OLUWA, ọmọ tí ó bí fún ọ yóo kú.”
15. Natani bá lọ sí ilé rẹ̀.OLUWA fi àìsàn ṣe ọmọ tí aya Uraya bí fún Dafidi.
16. Dafidi bá ń gbadura sí Ọlọrun pé kí ara ọmọ náà lè yá, ó ń gbààwẹ̀, ó sì ń sùn lórí ilẹ̀ lásán ní alaalẹ́.