Samuẹli Keji 10:8-15 BIBELI MIMỌ (BM)

8. Àwọn ará Amoni jáde sí àwọn ọmọ ogun Israẹli, wọ́n tò sí ẹnubodè wọn ní Raba, tíí ṣe olú ìlú wọn. Gbogbo àwọn ọmọ ogun, ará Siria tí wọ́n wá láti Soba ati Rehobu, ati àwọn ará Tobu ati ti Maaka, àwọn dá dúró ninu pápá.

9. Nígbà tí Joabu rí i pé àwọn ọ̀tá yóo gbógun ti àwọn níwájú ati lẹ́yìn, ó yan àwọn tí wọ́n jẹ́ akikanju jùlọ ninu àwọn ọmọ ogun Israẹli, ó ní kí wọ́n dojú kọ àwọn ará Siria.

10. Ó sì kó gbogbo àwọn ọmọ ogun rẹ̀ yòókù sábẹ́ ọ̀gágun Abiṣai, tí ó jẹ́ arakunrin rẹ̀, Abiṣai bá fi olukuluku sí ipò rẹ̀, wọ́n dojú kọ àwọn ará Amoni.

11. Joabu wí fún un pé, “Bí o bá rí i pé àwọn ará Siria fẹ́ ṣẹgun mi, wá ràn mí lọ́wọ́. Bí èmi náà bá sì rí i pé àwọn ará Amoni fẹ́ ṣẹgun rẹ, n óo wá ràn ọ́ lọ́wọ́.

12. Múra gírí, jẹ́ kí á fi gbogbo agbára wa jà fún àwọn eniyan wa ati fún ìlú Ọlọrun wa. Kí OLUWA wa ṣe èyí tí ó dára lójú rẹ̀.”

13. Joabu ati àwọn ọmọ ogun rẹ̀ tẹ̀síwájú láti gbógun ti àwọn ará Siria, àwọn ará Siria sì sá.

14. Nígbà tí àwọn ará Amoni rí i pé àwọn ará Siria ń sá lọ, àwọn náà sá fún Abiṣai, wọ́n sì pada sinu ìlú. Joabu bá pada lẹ́yìn àwọn ará Amoni, ó sì lọ sí Jerusalẹmu.

15. Nígbà tí àwọn ará Siria rí i pé, àwọn ọmọ ogun Israẹli ti ṣẹgun àwọn, wọ́n kó gbogbo àwọn ọmọ ogun wọn jọ.

Samuẹli Keji 10