Orin Solomoni 8:10-14 BIBELI MIMỌ (BM)

10. Ògiri ni mí,ọmú mi sì dàbí ilé-ìṣọ́;ní ojú olùfẹ́ mi,mo ní alaafia ati ìtẹ́lọ́rùn.

11. Solomoni ní ọgbà àjàrà kan,ní Baali Hamoni.Ó fi ọgbà náà fún àwọn tí wọn yá a,ó ní kí ẹnìkọ̀ọ̀kan wọn mú ẹgbẹrun (1,000) ìwọ̀n owó fadaka wá,fún èso ọgbà rẹ̀.

12. Èmi ni mo ni ọgbà àjàrà tèmi,ìwọ Solomoni lè ní ẹgbẹrun ìwọ̀n owó fadaka,kí àwọn tí wọn yá ọgbà sì ní igba.

13. Ìwọ tí ò ń gbé inú ọgbà,àwọn ẹlẹgbẹ́ mi ń dẹtí,jẹ́ kí n gbọ́ ọ̀rọ̀ rẹ.

14. Yára wá, olùfẹ́ mi,yára bí egbin, tabi ọ̀dọ́ akọ àgbọ̀nrín,sí orí àwọn òkè turari olóòórùn dídùn.

Orin Solomoni 8