10. Olùfẹ́ mi ló ni mí,èmi ni ọkàn rẹ̀ sì fẹ́.
11. Máa bọ̀, olùfẹ́ mi,jẹ́ kí á jáde lọ sinu pápá,kí á lọ sùn ní ìletò kan.
12. Kí á lọ sinu ọgbà àjàrà láàárọ̀ kutukutu,kí á wò ó bóyá àjàrà ti ń rúwé,bóyá ó ti ń tanná;kí á wò ó bóyá igi Pomegiranate ti ń tanná,níbẹ̀ ni n óo ti fi ìfẹ́ mi fún ọ.
13. Èso Mandirake ń tú òórùn dídùn jáde,ẹnu ọ̀nà wa kún fún oríṣìíríṣìí èso tí ó wuni,tí mo ti pèsè wọn dè ọ́, olùfẹ́ mi,ati tuntun ati èyí tó ti pẹ́ nílé.