1. Òdòdó Ṣaroni ni mí,ati òdòdó Lílì tí ó wà ninu àfonífojì.
2. Bí òdòdó lílì ti rí láàrin ẹ̀gún,ni olólùfẹ́ mi rí láàrin àwọn ọmọge.
3. Bí igi ápù ti rí láàrin àwọn igi igbó,ni olùfẹ́ mí rí láàrin àwọn ọmọkunrin.Pẹlu ìdùnnú ńlá ni mo fi jókòó lábẹ́ òjìji rẹ̀,èso rẹ̀ sì dùn lẹ́nu mi.
4. Ó mú mi wá sí ilé àsè ńlá,ìfẹ́ ni ọ̀págun rẹ̀ lórí mi.
5. Fún mi ni èso àjàrà gbígbẹ jẹ,kí ara mi mókun,fún mi ní èso ápù jẹ kí ara tù mí,nítorí pé, àìsàn ìfẹ́ ń ṣe mí.
6. Ó wù mí kí ọwọ́ òsì rẹ̀ wà ní ìgbèrí mi,kí ó sì fi ọwọ́ ọ̀tún rẹ̀ fà mí mọ́ra.
7. Mo kìlọ̀ fun yín, ẹ̀yin ọmọbinrin Jerusalẹmu,ní orúkọ egbin, ati ti àgbọ̀nrín pé,ẹ kò gbọdọ̀ jí ìfẹ́ títí yóo fi wù ú láti jí.
8. Mo gbọ́ ohùn olùfẹ́ mi, wò ó! Ó ń bọ̀,ó ń fò lórí àwọn òkè ńlá,ó sì ń bẹ́ lórí àwọn òkè kéékèèké.