Bí igi ápù ti rí láàrin àwọn igi igbó,ni olùfẹ́ mí rí láàrin àwọn ọmọkunrin.Pẹlu ìdùnnú ńlá ni mo fi jókòó lábẹ́ òjìji rẹ̀,èso rẹ̀ sì dùn lẹ́nu mi.