8. Ẹ jẹ́ kí ó ye yín,ẹ̀yin tí ẹ ya òpè jùlọ láàrin àwọn eniyan!Ẹ̀yin òmùgọ̀, nígbà wo ni ẹ óo gbọ́n?
9. Ṣé ẹni tí ó dá etí, ni kò ní gbọ́ràn?Àbí ẹni tí ó dá ojú, ni kò ní ríran?
10. Ṣé ẹni tí ń jẹ àwọn orílẹ̀-èdè níyà,ni kò ní jẹ yín níyà?Àbí ẹni tí ń fún eniyan ní ìmọ̀, ni kò ní ní ìmọ̀?
11. OLUWA mọ èrò ọkàn ọmọ eniyan,ó mọ̀ pé afẹ́fẹ́ lásán ni.
12. Ayọ̀ ń bẹ fún ẹni tí o bá báwí, OLUWA,tí o sì kọ́ ní òfin rẹ,
13. kí ó lè sinmi lọ́wọ́ ọjọ́ ìṣòro,títí tí a ó fi gbẹ́ kòtò fún eniyan burúkú.
14. Nítorí OLUWA kò ní kọ àwọn eniyan rẹ̀ sílẹ̀;kò ní ṣá àwọn eniyan ìní rẹ̀ tì;
15. nítorí pé ìdájọ́ òtítọ́ yóo pada jẹ́ ìpín àwọn olódodo,àwọn olóòótọ́ yóo sì máa tọ̀ ọ́ lẹ́yìn.
16. Ta ni yóo bá mi dìde sí àwọn eniyan burúkú?Ta ni yóo bá mi dìde sí àwọn aṣebi?