Orin Dafidi 89:1-2 BIBELI MIMỌ (BM)

1. OLUWA, n óo máa kọrin ìfẹ́ rẹ tí kì í yẹ̀ títí lae;n óo máa fi ẹnu mi kéde òtítọ́ rẹ láti ìran dé ìran.

2. Nítorí pé, a ti fi ìdí ìfẹ́ rẹ tí kì í yẹ̀ múlẹ̀ títí lae;o sì ti fi ìdí òtítọ́ rẹ múlẹ̀ bí ojú ọ̀run.

Orin Dafidi 89