Orin Dafidi 88:1-3 BIBELI MIMỌ (BM)

1. OLUWA, Ọlọrun, Olùgbàlà mi, mo ké pè ọ́ fún ìrànlọ́wọ́ ní ọ̀sán;mo ké níwájú rẹ ní òru.

2. Jẹ́ kí adura mi dé ọ̀dọ̀ rẹ;tẹ́tí sí igbe mi.

3. Nítorí pé ọkàn mi kún fún ìyọnu;mo sì súnmọ́ isà òkú.

Orin Dafidi 88