10. Nítorí pé o tóbi, o sì ń ṣe ohun ìyanu;ìwọ nìkan ni Ọlọrun.
11. OLUWA, kọ́ mi ní ọ̀nà rẹ,kí n lè máa rìn ninu òtítọ́ rẹ;kí n lè pa ọkàn pọ̀ láti máa bẹ̀rù orúkọ rẹ.
12. Gbogbo ọkàn ni mo fi dúpẹ́ lọ́wọ́ rẹ, OLUWA, Ọlọrun mi;n óo máa yin orúkọ rẹ lógo títí lae.
13. Nítorí ìfẹ́ rẹ tí kì í yẹ̀ tóbi sí mi;o ti yọ ọkàn mi kúrò ninu isà òkú.
14. Ọlọrun, àwọn agbéraga dìde sí mi;ẹgbẹ́ àwọn ìkà, aláìláàánú kan ń lépa ẹ̀mí mi;wọn kò sì bìkítà fún ọ.
15. Ṣugbọn ìwọ, OLUWA, ni Ọlọrun aláàánú ati olóore;o kì í tètè bínú, o sì kún fún ìfẹ́ tí kì í yẹ̀, ati òtítọ́.
16. Kọjú sí mi, kí o sì ṣàánú mi;fún èmi iranṣẹ rẹ ní agbára rẹ;kí o sì gba èmi ọmọ iranṣẹbinrin rẹ là.