1. Ọlọrun, àwọn orílẹ̀-èdè abọ̀rìṣà ti wọ inú ilẹ̀ ìní rẹ;wọ́n ti ba ilé mímọ́ rẹ jẹ́;wọ́n sì ti sọ Jerusalẹmu di ahoro.
2. Wọ́n ti fi òkú àwọn iranṣẹ rẹfún àwọn ẹyẹ ojú ọ̀run jẹ;wọ́n sì ti sọ òkú àwọn eniyan mímọ́ rẹ di ìjẹfún àwọn ẹranko ìgbẹ́.
3. Wọ́n ti da ẹ̀jẹ̀ wọn sílẹ̀ bí omi, káàkiri Jerusalẹmu;kò sì sí ẹni tí yóo gbé wọn sin.
4. A ti di ẹni ẹ̀gàn lójú àwọn aládùúgbò wa;àwọn tí ó yí wa ká ń fi wá ṣe yẹ̀yẹ́;wọ́n sì ń fi wá rẹ́rìn-ín.
5. Yóo ti pẹ́ tó, OLUWA?Ṣé títí ayé ni o óo máa bínú ni?Àbí owú rẹ yóo máa jó bí iná?
6. Tú ibinu rẹ sórí àwọn orílẹ̀-èdè tí kò mọ̀ ọ́,ati orí àwọn ìjọba tí kò sìn ọ́.
7. Nítorí pé wọ́n ti jẹ Jakọbu run;wọ́n sì ti sọ ibùgbé rẹ di ahoro.
8. Má gbẹ̀san ẹ̀ṣẹ̀ àwọn baba ńlá wa lára wa;yára, kí o ṣàánú wa,nítorí pé a ti rẹ̀ wá sílẹ̀ patapata.
9. Ràn wá lọ́wọ́, Ọlọrun Olùgbàlà wa,nítorí iyì orúkọ rẹ;gbà wá, sì dárí ẹ̀ṣẹ̀ wa jì wá,nítorí orúkọ rẹ.
10. Kí ló dé tí àwọn orílẹ̀-èdè yóo fi máa sọ pé,“Níbo ni Ọlọrun wọn wà?”Níṣojú wa, gbẹ̀san ẹ̀jẹ̀ àwọn iranṣẹ rẹ tí a palára àwọn orílẹ̀-èdè!