Orin Dafidi 78:4-7 BIBELI MIMỌ (BM)

4. A kò ní fi pamọ́ fún àwọn ọmọ wọn;a óo máa sọ ọ́ fún àwọn ìran tí ń bọ̀ lẹ́yìn–iṣẹ́ ńlá OLUWA ati ìṣe akọni rẹ̀,ati iṣẹ́ ìyanu tí ó ṣe.

5. Ó fi ìlànà lélẹ̀ fún ìdílé Jakọbu;ó gbé òfin kalẹ̀ fún àwọn ọmọ Israẹli.Ó pa á láṣẹ fún àwọn baba ńlá wa,pé kí wọ́n fi kọ́ àwọn ọmọ wọn.

6. Kí àwọn ìran tí ń bọ̀ lè mọ̀ ọ́n,àní, àwọn ọmọ tí a kò tíì bí,kí àwọn náà ní ìgbà tiwọnlè sọ ọ́ fún àwọn ọmọ wọn.

7. Kí wọn lè gbẹ́kẹ̀lé Ọlọrun,kí wọn má gbàgbé iṣẹ́ rẹ̀,kí wọn sì máa pa òfin rẹ̀ mọ́,

Orin Dafidi 78