Orin Dafidi 78:27-39 BIBELI MIMỌ (BM)

27. ó sì rọ̀jò ẹran sílẹ̀ fún wọn bí erùpẹ̀ ilẹ̀;àní, ẹyẹ abìyẹ́ bíi yanrìn etí òkun.

28. Ó mú kí wọn bọ́ sílẹ̀ láàrin ibùdó;yíká gbogbo àgọ́ wọn,

29. Àwọn eniyan náà jẹ, wọ́n sì yó;nítorí pé Ọlọrun fún wọn ní ohun tí ọkàn wọn fẹ́.

30. Ṣugbọn kí wọn tó tẹ́ ìfẹ́ ọkàn wọn lọ́rùn,àní, nígbà tí wọn ṣì ń jẹun lọ́wọ́.

31. Ọlọrun bínú sí wọn;ó pa àwọn tí ó lágbára jùlọ ninu wọn,ó sì lu àṣàyàn àwọn ọdọmọkunrin Israẹli pa.

32. Sibẹsibẹ wọ́n tún dẹ́ṣẹ̀;pẹlu gbogbo iṣẹ́ ìyanu rẹ̀, wọn kò gbàgbọ́.

33. Nítorí náà ó mú kí ọjọ́ ayé wọn pòórá bí afẹ́fẹ́;wọ́n sì lo ọjọ́ ayé wọn pẹlu ìjayà.

34. Nígbàkúùgbà tí ó bá ń pa wọ́n, wọn á wá a;wọn á ronupiwada, wọn á sì wá Ọlọrun tọkàntọkàn.

35. Wọn á ranti pé Ọlọrun ni àpáta ààbò wọn,ati pé Ọ̀gá Ògo ni olùràpadà wọn.

36. Ṣugbọn wọn kàn ń fi ẹnu wọn pọ́n ọn ni;irọ́ ni wọ́n sì ń pa fún un.

37. Ọkàn wọn kò dúró ṣinṣin lọ́dọ̀ rẹ̀;wọn kò sì pa majẹmu rẹ̀ mọ́.

38. Sibẹ, nítorí pé aláàánú ni, ó dárí ẹ̀ṣẹ̀ wọn jì wọ́n,kò sì pa wọ́n run;ní ọ̀pọ̀ ìgbà ni ó dáwọ́ ibinu rẹ̀ dúró,tí kò sì fi gbogbo ara bínú sí wọn.

39. Ó ranti pé ẹlẹ́ran ara ni wọ́n,afẹ́fẹ́ lásán tí ń fẹ́ kọjá lọ, tí kò sì ní pada mọ́.

Orin Dafidi 78