23. Sibẹ ó pàṣẹ fún ìkùukùu lókè,ó sì ṣí ìlẹ̀kùn ọ̀run sílẹ̀.
24. Ó rọ òjò mana sílẹ̀fún wọn láti jẹ,ó sì fún wọn ní ọkà ọ̀run.
25. Ọmọ eniyan jẹ lára oúnjẹ àwọn angẹli;Ọlọrun fún wọn ní oúnjẹ àjẹtẹ́rùn.
26. Ó mú kí afẹ́fẹ́ ìlà oòrùn fẹ́ ní ojú ọ̀run,ó sì fi agbára rẹ̀ darí afẹ́fẹ́ ìhà gúsù;
27. ó sì rọ̀jò ẹran sílẹ̀ fún wọn bí erùpẹ̀ ilẹ̀;àní, ẹyẹ abìyẹ́ bíi yanrìn etí òkun.
28. Ó mú kí wọn bọ́ sílẹ̀ láàrin ibùdó;yíká gbogbo àgọ́ wọn,
29. Àwọn eniyan náà jẹ, wọ́n sì yó;nítorí pé Ọlọrun fún wọn ní ohun tí ọkàn wọn fẹ́.
30. Ṣugbọn kí wọn tó tẹ́ ìfẹ́ ọkàn wọn lọ́rùn,àní, nígbà tí wọn ṣì ń jẹun lọ́wọ́.
31. Ọlọrun bínú sí wọn;ó pa àwọn tí ó lágbára jùlọ ninu wọn,ó sì lu àṣàyàn àwọn ọdọmọkunrin Israẹli pa.
32. Sibẹsibẹ wọ́n tún dẹ́ṣẹ̀;pẹlu gbogbo iṣẹ́ ìyanu rẹ̀, wọn kò gbàgbọ́.
33. Nítorí náà ó mú kí ọjọ́ ayé wọn pòórá bí afẹ́fẹ́;wọ́n sì lo ọjọ́ ayé wọn pẹlu ìjayà.
34. Nígbàkúùgbà tí ó bá ń pa wọ́n, wọn á wá a;wọn á ronupiwada, wọn á sì wá Ọlọrun tọkàntọkàn.
35. Wọn á ranti pé Ọlọrun ni àpáta ààbò wọn,ati pé Ọ̀gá Ògo ni olùràpadà wọn.
36. Ṣugbọn wọn kàn ń fi ẹnu wọn pọ́n ọn ni;irọ́ ni wọ́n sì ń pa fún un.
37. Ọkàn wọn kò dúró ṣinṣin lọ́dọ̀ rẹ̀;wọn kò sì pa majẹmu rẹ̀ mọ́.
38. Sibẹ, nítorí pé aláàánú ni, ó dárí ẹ̀ṣẹ̀ wọn jì wọ́n,kò sì pa wọ́n run;ní ọ̀pọ̀ ìgbà ni ó dáwọ́ ibinu rẹ̀ dúró,tí kò sì fi gbogbo ara bínú sí wọn.