Orin Dafidi 73:15-28 BIBELI MIMỌ (BM)

15. Bí mo bá ní, “N óo sọ̀rọ̀ báyìí,”n óo kó àwọn ọmọ rẹ ṣìnà.

16. Ṣugbọn nígbà tí mo rò bí nǹkan wọnyi ṣe lè yé mi,mo rí i pé iṣẹ́ tíí dáni lágara ni.

17. Àfi ìgbà tí mo wọ ibi mímọ́ Ọlọrun lọ,ni mo tó wá rí òye ìgbẹ̀yìn wọn.

18. Nítòótọ́ ibi tí ń yọ̀ ni ó gbé wọn lé,ó sì mú kí wọn ṣubú sinu ìparun.

19. Wò ó bí wọn ṣe parun lọ́gán,tí ìpayà sì gbá wọn lọ patapata.

20. Wọ́n dàbí àlá tíí pòórá nígbà tí eniyan bá ta jí.OLUWA, nígbà tí o bá jí gìrì, wọn óo pòórá.

21. Nígbà tí ọkàn mí bàjẹ́,tí ọ̀rọ̀ náà gbóná lára mi,

22. mo hùwà òmùgọ̀, n kò sì lóye,mo sì dàbí ẹranko lẹ́gbẹ̀ẹ́ rẹ.

23. Sibẹsibẹ nígbà gbogbo ni mo wà lọ́dọ̀ rẹ;o sì di ọwọ́ ọ̀tún mi mú.

24. Ò ń fi ìmọ̀ràn rẹ tọ́ mi sọ́nà;lẹ́yìn náà, o óo sì gbà mí sinu ògo.

25. Ta ni mo ní lọ́run lẹ́yìn rẹ?Kò sì sí ohun kan tí ó wù mí láyé yìí bíkòṣe ìwọ.

26. Àárẹ̀ lè mú ara ati ẹ̀mí mi,ṣugbọn Ọlọrun ni agbára ẹ̀mí mi,ati ìpín mi títí lae.

27. Ó dájú pé àwọn tí ó jìnnà sí ọ yóo ṣègbé,o óo sì pa àwọn tí ó bá ṣe alaiṣootọ sí ọ run.

28. Ní tèmi o, ó dára láti súnmọ́ Ọlọrun;mo ti fi ìwọ OLUWA Ọlọrun ṣe ààbò mi,kí n lè máa ròyìn gbogbo iṣẹ́ rẹ.

Orin Dafidi 73