9. Àwọn tí ń gbé aṣálẹ̀ yóo máa foríbalẹ̀ fún un;àwọn ọ̀tá rẹ̀ yóo sì máa fi ẹnu gbo ilẹ̀ níwájú rẹ̀.
10. Àwọn ọba Taṣiṣi ati àwọn ọba erékùṣù gbogboyóo máa san ìṣákọ́lẹ̀ fún un;àwọn ọba Ṣeba ati ti Seba yóo máa mú ẹ̀bùn wá.
11. Gbogbo àwọn ọba yóo máa wólẹ̀ fún un;gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè yóo sì máa sìn ín.
12. Nítorí pé a máa gba talaka tí ó bá ké pè é sílẹ̀;a sì máa gba àwọn tí ìyà ń jẹ sílẹ̀,ati àwọn tí kò ní olùrànlọ́wọ́.
13. A máa ṣíjú àánú wo àwọn aláìní ati talaka,a sì máa gba àwọn talaka sílẹ̀.
14. A máa gbà wọ́n lọ́wọ́ àwọn aninilára ati oníwà ipá,ẹ̀mí wọn sì ṣe iyebíye ní ojú rẹ̀.
15. Ẹ̀mí rẹ̀ yóo gùn,a óo máa fi wúrà Ṣeba ta á lọ́rẹ,a óo máa gbadura fún un nígbà gbogbo;a óo sì máa súre fún un tọ̀sán-tòru.
16. Ọkà yóo pọ̀ lóko,yóo máa mì lẹ̀gbẹ̀ lórí òkè;èso rẹ̀ yóo dàbí ti Lẹbanoni,eniyan yóo pọ̀ ní ìlú,bíi koríko ninu pápá.
17. Orúkọ ọba óo wà títí lae,òkìkí rẹ̀ óo sì máa kàn níwọ̀n ìgbà tí oòrùn bá ń ràn;àwọn eniyan óo máa fi orúkọ rẹ̀ súre fún ara wọn,gbogbo orílẹ̀-èdè óo sì máa pè é ní olóríire.