1. OLUWA, Ọlọrun mi, ìwọ ni mo sá di;gbà mí là, kí o sì yọ mí lọ́wọ́ àwọn tí ń lépa mi.
2. Kí wọn má baà fà mí ya bíi kinniun,kí wọn máa wọ́ mi lọ láìsí ẹni tí ó lè gbà mí sílẹ̀.
3. OLUWA, Ọlọrun mi, bí mo bá ṣe nǹkan yìí,bí iṣẹ́ ibi bá ń bẹ lọ́wọ́ mi,
4. bí mo bá fi ibi san án fún olóore,tabi tí mo bá kó ọ̀tá mi lẹ́rú láìnídìí,
5. jẹ́ kí ọ̀tá ó lé mi bá,kí ó tẹ̀ mí pa,kí ó sì bo òkú mi mọ́ ilẹ̀ẹ́lẹ̀.
6. OLUWA, fi ibinu dìde!Gbéra, kí o bá àwọn ọ̀tá mi jà ninu ìrúnú wọn;jí gìrì, Ọlọrun mi; ìwọ ni o ti fi ìlànà òdodo lélẹ̀.
7. Jẹ́ kí àwọn orílẹ̀-èdè ayé ó rọ̀gbà yí ọ ká,kí o sì máa jọba lé wọn lórí láti òkè wá.
8. OLUWA ló ń ṣe ìdájọ́ àwọn orílẹ̀-èdè ayé;dá mi láre, OLUWA, gẹ́gẹ́ bí òdodo mi ati ìwà pípé mi.
9. Ìwọ Ọlọrun Olódodo, tí o mọ èrò ati ìfẹ́ inú eniyan,fi òpin sí ìwà ibi àwọn eniyan burúkú,kí o sì fi ìdí àwọn olódodo múlẹ̀.
10. Ọlọrun ni aláàbò mi,òun níí gba àwọn ọlọ́kàn mímọ́ là.
11. Onídàájọ́ òdodo ni Ọlọrun,a sì máa bínú sí àwọn aṣebi lojoojumọ.