8. Aṣọ rẹ kún fún òórùn oríṣìíríṣìí turari,láti inú ààfin tí a fi eyín erin ṣe lọ́ṣọ̀ọ́ni wọ́n tí ń fi ohun èlò ìkọrin olókùn dá ọ lára yá.
9. Àwọn ọmọ ọba wà lára àwọn obinrin inú àgbàlá rẹ,ayaba dúró ní ọwọ́ ọ̀tún rẹ,ó fi ojúlówó wúrà ṣe ọ̀ṣọ́ sára.
10. Gbọ́, ìwọ ọmọbinrin, ronú kí o sì tẹ́tí sílẹ̀,gbàgbé àwọn eniyan rẹ ati ilé baba rẹ;
11. ẹwà rẹ yóo sì mú ọ wu ọba;òun ni oluwa rẹ, nítorí náà bu ọlá fún un.
12. Àwọn ará Tire yóo máa fi ẹ̀bùn wá ojurere rẹ,àní, àwọn eniyan tí wọ́n ní ọrọ̀ jùlọ.