14. O sọ wá di ẹni àmúpòwe láàrin àwọn orílẹ̀-èdè,ati ẹni yẹ̀yẹ́ láàrin gbogbo ayé.
15. Àbùkù mi wà lára mi tọ̀sán-tòru,ìtìjú sì ti bò mí.
16. Ọ̀rọ̀ àwọn apẹ̀gàn ati apeni-níjà ṣẹ mọ́ mi lára,lójú àwọn ọ̀tá mi ati àwọn tí ó fẹ́ gbẹ̀san.
17. Gbogbo nǹkan yìí ló ṣẹlẹ̀ sí wa,bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé a kò gbàgbé rẹ,bẹ́ẹ̀ ni a kò yẹ majẹmu rẹ.
18. Ọkàn wa kò pada lẹ́yìn rẹ,bẹ́ẹ̀ ni a kò yẹsẹ̀ kúrò ninu ìlànà rẹ,
19. sibẹ o fọ́ wa túútúú fún ìjẹ àwọn ẹranko,o sì fi òkùnkùn biribiri bò wá mọ́lẹ̀.
20. Bí ó bá jẹ́ pé a gbàgbé orúkọ Ọlọrun wa,tabi tí a bá bọ oriṣa,
21. ṣebí Ọlọrun ìbá ti mọ̀?Nítorí òun ni olùmọ̀ràn ọkàn.