Orin Dafidi 37:21-36 BIBELI MIMỌ (BM)

21. Bí eniyan burúkú bá yá owó, kò ní san;ṣugbọn ẹni rere ní ojú àánú, ó sì lawọ́.

22. Nítorí pé àwọn tí Ọlọrun bá bukun ni yóo jogún ilẹ̀ náà,ṣugbọn àwọn tí ó bá fi gégùn-ún yóo parun.

23. OLUWA níí darí ìgbésẹ̀ ẹni;a sì máa fi ẹsẹ̀ ẹni tí inú rẹ̀ bá dùn sí múlẹ̀.

24. Bí ó tilẹ̀ ṣubú, kò ní lulẹ̀ lógèdèǹgbé,nítorí OLUWA yóo gbé e ró.

25. Mo ti jẹ́ ọmọde rí; mo sì ti dàgbà:n kò tíì ri kí á kọ olódodo sílẹ̀,tabi kí ọmọ rẹ̀ máa tọrọ jẹ.

26. Olódodo ní ojú àánú, a sì máa yáni ní nǹkan,ayọ̀ ń bẹ fún àwọn ọmọ rẹ̀.

27. Ẹ yẹra fún ibi; ẹ sì máa ṣe rere;kí ẹ lè wà ní ààyè yín títí lae.

28. Nítorí OLUWA fẹ́ràn ẹ̀tọ́;kò ní kọ àwọn olùfọkànsìn rẹ̀ sílẹ̀.Yóo máa ṣọ́ wọn títí lae,ṣugbọn a óo pa àwọn ọmọ eniyan burúkú run.

29. Àwọn ẹni rere ni yóo jogún ilẹ̀ náà;wọn óo sì máa gbé orí rẹ̀ títí lae.

30. Ọ̀rọ̀ ọgbọ́n níí máa jáde lẹ́nu ẹni rere,a sì máa sọ ọ̀rọ̀ ẹ̀tọ́.

31. Òfin Ọlọrun rẹ̀ wà ní ọkàn rẹ̀;ìrìn ẹsẹ̀ rẹ̀ kì í yà kúrò níbẹ̀.

32. Eniyan burúkú ń ṣọ́ olódodo,ó ń wá ọ̀nà ati pa á.

33. OLUWA kò ní fi olódodo lé e lọ́wọ́,tabi kí ó jẹ́ kí á dá olódodo lẹ́bi ní ilé ẹjọ́.

34. Gbẹ́kẹ̀lé OLUWA, sì máa tọ ọ̀nà rẹ̀,yóo gbé ọ ga, kí o lè jogún ilẹ̀ náà;nígbà tí a bá pa àwọn eniyan burúkú run, o óo fojú rẹ rí i.

35. Mo ti rí eniyan burúkú tí ń halẹ̀ mọ́ni,tí ó ga bí igi kedari ti Lẹbanoni.

36. Ṣugbọn nígbà tí mo tún gba ibẹ̀ kọjá,mo wò ó, kò sí níbẹ̀ mọ́;mo wá a, ṣugbọn n kò rí i.

Orin Dafidi 37