1. Má gbé ara rẹ lọ́kàn gbóná nítorí àwọn eniyan burúkú;má sì jowú àwọn aṣebi;
2. nítorí pé kíákíá ni wọn yóo gbẹ bí i koríko;wọn óo sì rọ bí ewé.
3. Gbẹ́kẹ̀lé OLUWA; kí o sì máa ṣe rere.Máa gbe ilẹ̀ náà; ewu kò sì ní wu ọ́.
4. Jẹ́ kí inú rẹ máa dùn ninu OLUWA;yóo sì fún ọ ní ohun tí ọkàn rẹ ń fẹ́.
5. Fi ọ̀nà rẹ lé OLUWA lọ́wọ́;gbẹ́kẹ̀lé e, yóo sì ṣe ohun tí ó yẹ.
6. Yóo mú kí ìdáláre rẹ tàn bí ìmọ́lẹ̀;ẹ̀tọ́ rẹ yóo sì hàn kedere bí ọ̀sán gangan.
7. Dákẹ́ jẹ́ẹ́ níwájú OLUWA; fi sùúrù gbẹ́kẹ̀lé e.Má gbé ara rẹ lọ́kàn gbóná nítorí ẹni tí nǹkan ń dára fún;tabi nítorí ẹni tí ń gbèrò ibi, tí ó sì ń ṣe é.
8. Yẹra fún ibinu; sì yàgò fún ìrúnú.Má gbé ara rẹ lọ́kàn gbóná; ibi ni àyọrísí rẹ̀.
9. Nítorí pé a óo pa àwọn eniyan burúkú run;ṣugbọn àwọn tí ó gbẹ́kẹ̀lé OLUWAni yóo jogún ilẹ̀ náà.
10. Ẹ fún eniyan burúkú ní ìgbà díẹ̀ sí i, yóo pòórá;ẹ̀ báà wá a títí ní ààyè rẹ̀, kò ní sí níbẹ̀.
11. Ṣugbọn àwọn oníwà pẹ̀lẹ́ ni yóo jogún ilẹ̀ náà:wọn óo máa gbádùn ara wọn;wọn óo sì ní alaafia lọpọlọpọ.
12. Eniyan burúkú dìtẹ̀ mọ́ olódodo;ó sì ń wò ó bíi kíkú bíi yíyè.