Orin Dafidi 33:14-17 BIBELI MIMỌ (BM)

14. láti orí ìtẹ́ rẹ̀ tí ó gúnwà sí,ó wo gbogbo aráyé.

15. Òun ni ó dá ọkàn gbogbo wọn,tí ó sì ń mójútó gbogbo ìṣe wọn.

16. Kì í ṣe pípọ̀ tí àwọn ọmọ ogun pọ̀ ní ń gba ọba là;kì í sì í ṣe ọ̀pọ̀ agbára níí gba jagunjagun là.

17. Asán ni igbẹkẹle agbára ẹṣin ogun;kìí ṣe agbára tí ẹṣin ní, ló lè gbani là.

Orin Dafidi 33