Orin Dafidi 33:1-4 BIBELI MIMỌ (BM)

1. Ẹ máa yọ̀ ninu OLUWA, ẹ̀yin olódodo!Yíyin OLUWA ni ó yẹ ẹ̀yin olóòótọ́.

2. Ẹ fi gòjé yin OLUWA,ẹ fi hapu olókùn mẹ́wàá kọ orin sí i.

3. Ẹ kọ orin titun sí i,ẹ fi ohun èlò ìkọrin olókùn dárà,kí ẹ sì hó ìhó ayọ̀.

4. Nítorí ọ̀rọ̀ OLUWA dúró ṣinṣin;òtítọ́ sì ni ó fi ń ṣe gbogbo iṣẹ́ rẹ̀.

Orin Dafidi 33