Orin Dafidi 29:1-3 BIBELI MIMỌ (BM)

1. Ẹ̀yin ẹ̀dá ọ̀run, ẹ fi ògo fún OLUWA,ẹ gbé agbára rẹ̀ lárugẹ.

2. Ẹ fún OLUWA ní ògo tí ó yẹ orúkọ rẹ̀,ẹ máa sin OLUWA ninu ẹwà mímọ́ rẹ̀.

3. À ń gbọ́ ohùn OLUWA lójú omi òkun,Ọlọrun ológo ń sán ààrá,Ọlọrun ń sán ààrá lójú alagbalúgbú omi.

Orin Dafidi 29