Orin Dafidi 27:1-4 BIBELI MIMỌ (BM)

1. OLUWA ni ìmọ́lẹ̀ ati ìgbàlà mi;ta ni n óo bẹ̀rù?OLUWA ni ààbò ẹ̀mí mi,ẹ̀rù ta ni yóo bà mí?

2. Nígbà tí àwọn aṣebi bá ń gbógun bọ̀ wá bá mi,tí wọ́n fẹ́ pa mí,àwọn alátakò ati àwọn ọ̀tá mi,wọn óo kọsẹ̀, wọn óo sì ṣubú.

3. Bí ogun tilẹ̀ dó tì míàyà mi kò ní já.Bí wọ́n tilẹ̀ gbé ogun wá bá mi,sibẹ, ọkàn mi kò ní mì.

4. Ohun kan ni mo ti tọrọ lọ́dọ̀ OLUWA,òun ni n óo sì máa lépa:Kí n lè máa gbé inú ilé OLUWAní gbogbo ọjọ́ ayé mi,kí n lè máa wo ẹwà OLUWA,kí n sì máa fi tọkàntọkàn sìn ín ninu tẹmpili rẹ̀.

Orin Dafidi 27