Orin Dafidi 18:40-45 BIBELI MIMỌ (BM)

40. O mú kí àwọn ọ̀tá mi máa sá níwájú mi,mo sì pa àwọn tí ó kórìíra mi run.

41. Wọ́n kígbe pé, “Ẹ gbà wá o!”Ṣugbọn kò sí ẹni tí ó gbà wọ́n,wọ́n ké pe OLUWA, ṣugbọn kò dá wọn lóhùn.

42. Mo lọ̀ wọ́n lúbúlúbú bí eruku tí afẹ́fẹ́ ń gbá lọ,mo dà wọ́n nù bí ẹni da omi ẹrẹ̀ nù.

43. O gbà mí lọ́wọ́ ọ̀tẹ̀ àwọn eniyan,o fi mí ṣe olórí àwọn orílẹ̀-èdè;àwọn orílẹ̀-èdè tí n kò mọ̀ rí sì ń sìn mí.

44. Bí wọ́n bá ti gbúròó mi ni wọ́n ń gbọ́ràn sí mi lẹ́nu;àwọn àjèjì ń fi ìbẹ̀rùbojo tẹríba, wọ́n ń wá ojurere mi.

45. Àyà pá àwọn àlejò,wọ́n sì fi ìbẹ̀rùbojo sá jáde kúrò ní ibi tí wọ́n sápamọ́ sí.

Orin Dafidi 18