Orin Dafidi 18:30-41 BIBELI MIMỌ (BM)

30. Ní ti Ọlọrun, ọ̀nà rẹ̀ pé,pípé ni ọ̀rọ̀ OLUWA;òun sì ni ààbò fún gbogbo àwọn tí ó sá di í.

31. Ta tún ni Ọlọrun, bíkòṣe OLUWA?Àbí, ta ni àpáta, àfi Ọlọrun wa?

32. Ọlọrun tí ó gbé agbára wọ̀ mí,tí ó sì mú ọ̀nà mi pé.

33. Ó fi eré sí mi lẹ́sẹ̀ bíi ti àgbọ̀nrín,ó sì fún mi ní ààbò ní ibi ìsásí.

34. Ó kọ́ mi ní ogun jíjàtóbẹ́ẹ̀ tí mo fi lè fa ọrun idẹ.

35. O ti fún mi ní asà ìgbàlà rẹ,ọwọ́ ọ̀tún rẹ ni ó gbé mi ró,ìrànlọ́wọ́ rẹ sì ni ó sọ mí di ẹni ńlá.

36. O la ọ̀nà tí ó gbòòrò fún mi,n kò sì fi ẹsẹ̀ rọ́.

37. Mo lé àwọn ọ̀tá mi, ọwọ́ mi sì tẹ̀ wọ́n,n kò bojú wẹ̀yìn títí a fi pa wọ́n run.

38. Mo ṣá wọn lọ́gbẹ́, wọn kò lè dìde,wọ́n ṣubú sí abẹ́ ẹsẹ̀ mi.

39. O gbé agbára ogun wọ̀ mí;o sì mú àwọn tí ó dìde sí mi wólẹ̀ lábẹ́ ẹsẹ̀ mi.

40. O mú kí àwọn ọ̀tá mi máa sá níwájú mi,mo sì pa àwọn tí ó kórìíra mi run.

41. Wọ́n kígbe pé, “Ẹ gbà wá o!”Ṣugbọn kò sí ẹni tí ó gbà wọ́n,wọ́n ké pe OLUWA, ṣugbọn kò dá wọn lóhùn.

Orin Dafidi 18