1. Ẹ yin OLUWA!Ẹ kọ orin titun sí OLUWA,ẹ kọrin ìyìn sí i ninu àwùjọ àwọn olóòótọ́.
2. Kí Israẹli máa yọ̀ ninu Ẹlẹ́dàá rẹ̀,kí àwọn ọmọ Sioni máa fò fún ayọ̀ pé àwọn ní Ọba.
3. Kí wọn máa fi ijó yin orúkọ rẹ̀,kí wọn máa fi ìlù ati hapu kọ orin aládùn sí i.
4. Nítorí pé inú OLUWA dùn sí àwọn eniyan rẹ̀,a sì máa fi ìṣẹ́gun dé àwọn onírẹ̀lẹ̀ ládé.