5. Ayọ̀ ń bẹ fún ẹni tí ó fi Ọlọrun Jakọbu ṣe olùrànlọ́wọ́ rẹ̀,tí ó gbójú lé OLUWA, Ọlọrun rẹ̀.
6. Ọlọrun tí ó dá ọ̀run ati ayé,òkun ati gbogbo ohun tí ó wà ninu rẹ̀;Ọlọrun tíí máa ń pa àdéhùn rẹ̀ mọ́ títí lae,
7. ẹni tíí máa ń dá ẹjọ́ òdodo fún àwọn tí a ni lára;tí ń fún àwọn tí ebi ń pa ní oúnjẹ,OLUWA tíí tú àwọn tí ó wà ninu ìdè sílẹ̀.
8. A máa la ojú àwọn afọ́jú,a máa gbé àwọn tí a tẹrí wọn ba dúró;ó fẹ́ràn àwọn olódodo.
9. OLUWA ni olùṣọ́ àwọn àlejò,òun ni alátìlẹ́yìn àwọn opó ati aláìníbaba,ṣugbọn a máa da ète àwọn eniyan burúkú rú.
10. OLUWA yóo jọba títí lae,Sioni, Ọlọrun rẹ yóo jọba láti ìran dé ìran.Ẹ yin OLUWA.