2. Títí di ìgbà wo ni ọkàn mi yóo gbọgbẹ́tí ìbànújẹ́ yóo gba ọkàn mi kan, ní gbogbo ìgbà?Títí di ìgbà wo ni àwọn ọ̀tá mi yóo máa yọ̀ mí?
3. Bojúwò mí, kí o sì dá mi lóhùn, OLUWA, Ọlọrun mi.Tan ìmọ́lẹ̀ sí ojú mi, kí n má baà sun oorun ikú.
4. Kí ọ̀tá mi má baà wí pé, “Mo ti rẹ́yìn rẹ̀.”Kí àwọn tí ó kórìíra mi má baà yọ̀ bí mo bá ṣubú.
5. Ṣùgbọ́n èmi gbẹ́kẹ̀lé ìfẹ́ rẹ tí kì í yẹ̀;n óo máa yọ̀ nítorí pé o óo gbà mí.
6. N óo máa kọrin sí ọ, OLUWA,nítorí o ṣeun fún mi lọpọlọpọ.