Orin Dafidi 118:12-27 BIBELI MIMỌ (BM)

12. Wọ́n ṣùrù bò mí bí oyin,ṣugbọn kíá ni wọ́n kú bí iná ìṣẹ́pẹ́;ní orúkọ OLUWA, mo pa wọ́n run.

13. Wọ́n gbógun tì mí gidigidi, tóbẹ́ẹ̀ tí mo fẹ́rẹ̀ ṣubú,ṣugbọn OLUWA ràn mí lọ́wọ́.

14. OLUWA ni agbára ati orin mi,ó ti di olùgbàlà mi.

15. Ẹ gbọ́ orin ayọ̀ ìṣẹ́gun,ninu àgọ́ àwọn olódodo.“Ọwọ́ ọ̀tún OLUWA ti ṣe iṣẹ́ agbára ńlá.

16. A gbé ọwọ́ ọ̀tún OLUWA ga,ọwọ́ ọ̀tún OLUWA ti ṣe iṣẹ́ agbára ńlá!”

17. N ò ní kú, yíyè ni n óo yè,n óo sì máa fọnrere nǹkan tí OLUWA ṣe.

18. OLUWA jẹ mí níyà pupọ,ṣugbọn kò fi mí lé ikú lọ́wọ́.

19. Ṣí ìlẹ̀kùn òdodo fún mi,kí n lè gba ibẹ̀ wọlé,kí n sì máa dúpẹ́ lọ́wọ́ OLUWA.

20. Èyí ni ẹnu ọ̀nà OLUWA;àwọn olódodo yóo gba ibẹ̀ wọlé.

21. Mo dúpẹ́ lọ́wọ́ rẹ, nítorí pé o gbọ́ ohùn mi,o sì ti di olùgbàlà mi.

22. Òkúta tí àwọn ọ̀mọ̀lé kọ̀ sílẹ̀,ni ó di pataki igun ilé.

23. OLUWA ló ṣe èyí;ó sì jẹ́ ohun ìyanu lójú wa.

24. Òní ni ọjọ́ tí OLUWA dá,ẹ jẹ́ kí á máa yọ̀, kí inú wa sì máa dùn.

25. OLUWA, à ń bẹ̀ ọ́, gbà wá,OLUWA, à ń bẹ̀ ọ́, jẹ́ kí á ṣe àṣeyege.

26. Ayọ̀ ń bẹ fún ẹni tí ń bọ̀ wá ní orúkọ OLUWA,láti inú ilé rẹ ni a ti ń yìn ọ́, OLUWA.

27. OLUWA ni Ọlọrun, ó sì ti tan ìmọ́lẹ̀ sí wa.Pẹlu ẹ̀ka igi lọ́wọ́, ẹ bẹ̀rẹ̀ ayẹyẹ ìwọ́de ẹbọ náà,títí dé ibi ìwo pẹpẹ.

Orin Dafidi 118