Orin Dafidi 106:1-12 BIBELI MIMỌ (BM)

1. Ẹ yin OLUWA!Ẹ dúpẹ́ lọ́wọ́ OLUWA, nítorí pé ó ṣeunnítorí ìfẹ́ rẹ̀ tí kì í yẹ̀ wà títí lae.

2. Ta ló lè sọ iṣẹ́ agbára OLUWA tán?Ta ló sì lè fi gbogbo ìyìn rẹ̀ hàn?

3. Ayọ̀ ń bẹ fún àwọn tí ń ṣe ẹ̀tọ́,àwọn tí ń ṣe ohun tí ó tọ̀nà nígbà gbogbo.

4. Ranti mi, OLUWA, nígbà tí o bá ńṣí ojurere wo àwọn eniyan rẹ.Ràn mí lọ́wọ́ nígbà tí o bá ń gbà wọ́n là.

5. Kí n lè rí ire àwọn àyànfẹ́ rẹkí n lè ní ìpín ninu ayọ̀ àwọn eniyan rẹ,kí n sì lè máa ṣògo pẹlu àwọn tí ó jẹ́ eniyan ìní rẹ.

6. A ti ṣẹ̀, àtàwa, àtàwọn baba wa,a ti ṣe àìdára, a sì ti hùwà burúkú.

7. Nígbà tí àwọn baba ńlá wa wà ní Ijipti,wọn kò náání iṣẹ́ ìyanu rẹ,wọn kò sì ranti bí ìfẹ́ rẹ tí kì í yẹ̀ ti pọ̀ tó.Ṣugbọn wọ́n ṣọ̀tẹ̀ sí Ọ̀gá Ògo lẹ́bàá òkun pupa.

8. Sibẹsibẹ, ó gbà wọ́n là, nítorí orúkọ rẹ̀;kí ó lè fi títóbi agbára rẹ̀ hàn.

9. Ó bá òkun pupa wí, òkun pupa gbẹ,ó sì mú wọn la ibú já bí ẹni rìn ninu aṣálẹ̀.

10. Ó gbà wọ́n là lọ́wọ́ àwọn tí ó kórìíra wọn,ó sì kó wọn yọ lọ́wọ́ àwọn ọ̀tá wọn.

11. Omi bo àwọn ọ̀tá wọn,ẹyọ ẹnìkan kò sì là.

12. Nígbà náà ni wọ́n tó gba ọ̀rọ̀ rẹ̀ gbọ́,wọ́n sì kọrin yìn ín.

Orin Dafidi 106