1. Yin OLUWA, ìwọ ọkàn mi,OLUWA, Ọlọrun mi, ó tóbi pupọ,ọlá ati iyì ni ó wọ̀ bí ẹ̀wù.
2. Ó fi ìmọ́lẹ̀ bora bí aṣọ,ó ta ojú ọ̀run bí ẹni taṣọ.
3. Ìwọ tí o tẹ́ àjà ibùgbé rẹ sórí omi,tí o fi ìkùukùu ṣe kẹ̀kẹ́ ogun rẹ,tí o sì ń lọ geere lórí afẹ́fẹ́.
4. Ìwọ tí o fi ẹ̀fúùfù ṣe iranṣẹ,tí o sì fi iná ati ahọ́n iná ṣe òjíṣẹ́ rẹ.
5. Ìwọ tí o gbé ayé kalẹ̀ lórí ìpìlẹ̀ rẹ̀,tí kò sì le yẹ̀ laelae.
6. O fi ibú omi bò ó bí aṣọ,omi sì borí àwọn òkè ńlá.