Orin Dafidi 103:2-9 BIBELI MIMỌ (BM)

2. Yin OLUWA, ìwọ ọkàn mi,má sì ṣe gbàgbé gbogbo oore rẹ̀,

3. ẹni tí ó ń dárí gbogbo ẹ̀ṣẹ̀ rẹ jì ọ́,tí ó ń wo gbogbo àrùn rẹ sàn;

4. ẹni tí ó ń yọ ẹ̀mí rẹ kúrò ninu ọ̀fìn,tí ó fi ìfẹ́ rẹ̀ tí kì í yẹ̀ ati àánú dé ọ ládé.

5. Ẹni tí ó ń fi ohun dáradára tẹ́ ọ lọ́rùn,tí ó fi ń sọ agbára ìgbà èwe rẹ dọ̀tun bíi ti idì.

6. OLUWA a máa dáni lárea sì máa ṣe ìdájọ́ òdodo fún gbogboàwọn tí a ni lára.

7. Ó fi ọ̀nà rẹ̀ han Mose,ó sì ṣe iṣẹ́ ìyanu rẹ̀ han àwọn ọmọ Israẹli.

8. Aláàánú ati olóore ni OLUWA,kì í tètè bínú, ìfẹ́ rẹ̀ tí kì í yẹ̀ sì pọ̀.

9. Kì í fi ìgbà gbogbo báni wí,bẹ́ẹ̀ ni ibinu rẹ̀ kì í pẹ́ títí ayé.

Orin Dafidi 103