12. Bí ìlà oòrùn ti jìnnà sí ìwọ oòrùn,bẹ́ẹ̀ ni ó mú ẹ̀ṣẹ̀ wa jìnnà sí wa.
13. Bí baba ti máa ń ṣàánú àwọn ọmọ rẹ̀,bẹ́ẹ̀ ni OLUWA máa ń ṣàánú àwọntí ó bá bẹ̀rù rẹ̀.
14. Nítorí ó mọ ẹ̀dá wa;ó ranti pé erùpẹ̀ ni wá.
15. Ọjọ́ ayé ọmọ eniyan dàbí ti koríko,eniyan a sì máa gbilẹ̀ bí òdòdó inú igbó;
16. ṣugbọn bí afẹ́fẹ́ bá ti fẹ́ kọjá lórí rẹ̀,á rẹ̀ dànù,ààyè rẹ̀ kò sì ní ranti rẹ̀ mọ́.
17. Ṣugbọn títí ayé ni ìfẹ́ OLUWA tí kì í yẹ̀,sí àwọn tí ó bẹ̀rù rẹ̀,òdodo rẹ̀ wà lára arọmọdọmọ wọn.
18. Ó wà lára àwọn tí ó ń pa majẹmu rẹ̀ mọ́,tí wọn sì ń ranti láti pa òfin rẹ̀ mọ́.