10. Kì í ṣe sí wa gẹ́gẹ́ bí ẹ̀ṣẹ̀ wa,bẹ́ẹ̀ ni kì í san án fún wa bí àìdára wa.
11. Nítorí bí ọ̀run ti jìnnà sí ilẹ̀,bẹ́ẹ̀ ni ìfẹ́ rẹ̀ tí kì í yẹ̀ ṣe tóbi tósí àwọn tí ó bẹ̀rù rẹ̀.
12. Bí ìlà oòrùn ti jìnnà sí ìwọ oòrùn,bẹ́ẹ̀ ni ó mú ẹ̀ṣẹ̀ wa jìnnà sí wa.
13. Bí baba ti máa ń ṣàánú àwọn ọmọ rẹ̀,bẹ́ẹ̀ ni OLUWA máa ń ṣàánú àwọntí ó bá bẹ̀rù rẹ̀.
14. Nítorí ó mọ ẹ̀dá wa;ó ranti pé erùpẹ̀ ni wá.
15. Ọjọ́ ayé ọmọ eniyan dàbí ti koríko,eniyan a sì máa gbilẹ̀ bí òdòdó inú igbó;
16. ṣugbọn bí afẹ́fẹ́ bá ti fẹ́ kọjá lórí rẹ̀,á rẹ̀ dànù,ààyè rẹ̀ kò sì ní ranti rẹ̀ mọ́.
17. Ṣugbọn títí ayé ni ìfẹ́ OLUWA tí kì í yẹ̀,sí àwọn tí ó bẹ̀rù rẹ̀,òdodo rẹ̀ wà lára arọmọdọmọ wọn.
18. Ó wà lára àwọn tí ó ń pa majẹmu rẹ̀ mọ́,tí wọn sì ń ranti láti pa òfin rẹ̀ mọ́.
19. OLUWA ti gbé ìtẹ́ rẹ̀ kalẹ̀ lọ́run,ó sì jọba lórí ohun gbogbo.
20. Ẹ yin OLUWA, ẹ̀yin angẹli rẹ̀,ẹ̀yin alágbára tí ẹ̀ ń ṣe ìfẹ́ rẹ̀,tí ẹ sì ń fetí sí ọ̀rọ̀ rẹ̀.