1. Gbọ́ adura mi, OLUWA;kí o sì jẹ́ kí igbe mi dé ọ̀dọ̀ rẹ.
2. Má yọwọ́ lọ́ràn mi lọ́jọ́ ìṣòro!Dẹtí sí adura mi;kí o sì tètè dá mi lóhùn nígbà tí mo bá ké pè ọ́.
3. Nítorí ọjọ́ ayé mi ń kọjá lọ bí èéfín,eegun mi gbóná bí iná ààrò.
4. Ìdààmú bá ọkàn mi, mo rọ bíi koríko,tóbẹ́ẹ̀ tí mo gbàgbé láti jẹun.
5. Nítorí igbe ìrora mi,mo rù kan eegun.
6. Mo dàbí igúnnugún inú aṣálẹ̀,àní, bí òwìwí inú ahoro.
7. Mo dùbúlẹ̀ láìlè sùn,mo dàbí ẹyẹ tí ó dá wà lórí òrùlé.
8. Àwọn ọ̀tá ń fi mí ṣe yẹ̀yẹ́ tọ̀sán-tòru,àwọn tí wọn ń pẹ̀gàn mi ń fi orúkọ mi ṣépè.
9. Mò ń jẹ eérú bí oúnjẹ,mo sì ń mu omijé mọ́ omi
10. nítorí ìrúnú ati ibinu rẹ;o gbé mi sókè,o sì jù mí nù.
11. Ọjọ́ ayé mi ń lọ bí òjìji àṣáálẹ́,mo sì ń rọ bíi koríko.
12. Bẹ́ẹ̀ sì ni ìwọ OLUWA gúnwà títí lae,ọlá rẹ sì wà láti ìran dé ìran.
13. Ìwọ óo dìde, o óo sì ṣàánú Sioni,nítorí ó tó àkókò láti fi ojú àánú wò ó.Àkókò tí o dá tó.
14. Nítorí àwọn òkúta rẹ̀ ṣe iyebíye lójú àwọn iranṣẹ rẹ,àánú rẹ̀ sì ṣeni bí ó tilẹ̀ ti wó dà sinu erùpẹ̀.
15. Àwọn orílẹ̀-èdè yóo máa bẹ̀rù orúkọ OLUWA,gbogbo ọba ayé ni yóo sì máa bẹ̀rù ògo rẹ̀.
16. Nítorí OLUWA yóo tún Sioni kọ́,yóo sì fara hàn ninu ògo rẹ̀.