Ọbadaya 1:1-5 BIBELI MIMỌ (BM)

1. Ìran tí Ọbadaya rí nìyí, OLUWA Ọlọrun sọ nípa Edomu pé:A ti gbọ́ ìròyìn láti ọ̀dọ̀ OLUWA,ó sì ti rán iranṣẹ rẹ̀ sí àwọn orílẹ̀-èdè pé:“Ẹ múra, ẹ jẹ́ kí á lọ bá Edomu jagun!”

2. Ó sọ fún Edomu pé, “Wò ó, n óo sọ ọ́ di yẹpẹrẹ láàrin àwọn orílẹ̀-èdè yòókù;gbogbo ayé pátá ni yóo máa fi ọ́ ṣẹ̀sín.

3. Ìgbéraga rẹ ti tàn ọ́ jẹ,ìwọ tí ò ń gbé inú pàlàpálá òkúta,tí ibùgbé rẹ wà lórí òkè gíga,tí o sì ń wí ninu ọkàn rẹ pé, ‘Ta ni ó lè fà mí lulẹ̀?’

4. Bí o tilẹ̀ fò lọ sókè bí ẹyẹ idì,tí ó tẹ́ ìtẹ́ rẹ̀ sí ààrin àwọn ìràwọ̀,láti òkè náà ni n óo ti fà ọ́ lulẹ̀.Èmi OLUWA ni mo sọ bẹ́ẹ̀.

5. “Bí àwọn olè bá wá bá ọ lóru,tí àwọn ọlọ́ṣà bá wá ká ọ mọ́lé lọ́gànjọ́,ṣé wọn kò ní hàn ọ́ léèmọ̀?Ṣebí ohun tí wọ́n bá fẹ́ ninu ẹrù rẹ ni wọn óo kó?Bí àwọn tí wọn ń kórè àjàrà bá wá sọ́dọ̀ rẹ,ṣebí wọn a máa fi díẹ̀ sílẹ̀?

Ọbadaya 1