38. Balaamu dáhùn pé, “Wíwá tí mo wá yìí, èmi kò ní agbára láti sọ ohunkohun bíkòṣe ohun tí OLUWA bá sọ fún mi.”
39. Balaamu bá Balaki lọ sí ìlú Kiriati-husotu.
40. Níbẹ̀ ni Balaki ti fi akọ mààlúù ati aguntan ṣe ìrúbọ, ó sì fún Balaamu ati àwọn àgbààgbà tí wọ́n wà pẹlu rẹ̀ ninu ẹran náà.
41. Ní òwúrọ̀ ọjọ́ keji, Balaki mú Balaamu lọ sí ibi gegele Bamotu Baali níbi tí ó ti lè rí apá kan àwọn ọmọ Israẹli.