30. Kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ náà dáhùn pé, “Ṣebí kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ rẹ ni mí, tí o sì ti ń gùn mí láti iye ọjọ́ yìí títí di òní? Ǹjẹ́ mo hu irú ìwà báyìí sí ọ rí?”Balaamu dáhùn pé, “Rárá o.”
31. Nígbà náà ni OLUWA la Balaamu lójú láti rí angẹli tí ó dúró lójú ọ̀nà pẹlu idà lọ́wọ́ rẹ̀, Balaamu sì dojúbolẹ̀.
32. Angẹli náà bèèrè lọ́wọ́ rẹ̀ pé, “Kí ló dé tí o fi lu kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ rẹ nígbà mẹta? Mo wá láti dínà fún ọ nítorí pé kò yẹ kí o rin ìrìn àjò yìí.
33. Kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ rẹ rí mi, ó sì yà fún mi nígbà mẹta, bí bẹ́ẹ̀ bá kọ́, ǹ bá ti pa ọ́, ǹ bá sì dá òun sí.”
34. Balaamu dá angẹli náà lóhùn pé, “Mo ti dẹ́ṣẹ̀, n kò sì mọ̀ pé o dúró lójú ọ̀nà láti dínà fún mi. Ó dára, bí o kò bá fẹ́ kí n lọ, n óo pada.”
35. Angẹli OLUWA sì dáhùn pé, “Máa bá àwọn ọkunrin náà lọ, ṣugbọn ohun tí mo bá sọ fún ọ ni kí o sọ.” Balaamu sì bá wọn lọ.