24. Angẹli náà tún dúró ní ọ̀nà tóóró láàrin ọgbà àjàrà meji, ògiri sì wà ní ìhà mejeeji.
25. Nígbà tí kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ náà rí i, ó fún ara rẹ̀ mọ́ ògiri, ẹsẹ̀ Balaamu sì fún mọ́ ògiri pẹlu, Balaamu bá tún lù ú.
26. Lẹ́ẹ̀kan sí i, angẹli náà lọ siwaju, ó dúró ní ọ̀nà tóóró kan níbi tí kò sí ààyè rárá láti yà sí.
27. Nígbà tí kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ náà rí angẹli náà, ó wó lulẹ̀ lábẹ́ Balaamu. Inú bí Balaamu gidigidi, ó sì fi ọ̀pá rẹ̀ na kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ náà.
28. Nígbà náà ni OLUWA la kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ náà lóhùn ó sì sọ̀rọ̀ bí eniyan, ó sì sọ fún Balaamu pé, “Kí ni mo fi ṣe ọ́ tí o fi lù mí nígbà mẹta?”
29. Balaamu dáhùn pé, “Nítorí tí ò ń fi mí ṣẹ̀sín, bí ó bá jẹ́ pé idà wà lọ́wọ́ mi ni, ǹ bá ti pa ọ́.”
30. Kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ náà dáhùn pé, “Ṣebí kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ rẹ ni mí, tí o sì ti ń gùn mí láti iye ọjọ́ yìí títí di òní? Ǹjẹ́ mo hu irú ìwà báyìí sí ọ rí?”Balaamu dáhùn pé, “Rárá o.”