20. Ní òru ọjọ́ náà, Ọlọrun tọ Balaamu wá, ó ní, “Bí ó bá jẹ́ pé àwọn ọkunrin wọnyi wá bẹ̀ ọ́ pé kí o bá wọn lọ, máa bá wọn lọ, ṣugbọn ohun tí mo bá sọ fún ọ ni o gbọdọ̀ ṣe.”
21. Ní òwúrọ̀ ọjọ́ keji, Balaamu di kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ rẹ̀ ní gàárì, ó sì bá àwọn àgbààgbà Moabu lọ.
22. OLUWA bínú sí Balaamu nítorí pé ó bá wọn lọ. Bí ó ti ń lọ lórí kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ rẹ̀ pẹlu àwọn iranṣẹ rẹ̀ meji, angẹli OLUWA dúró ní ojú ọ̀nà rẹ̀ ó dínà fún un.
23. Nígbà tí kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ náà rí angẹli tí ó dúró ní ọ̀nà pẹlu idà ní ọwọ́ rẹ̀, ó yà kúrò ní ojú ọ̀nà sinu igbó. Balaamu lu kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ náà láti darí rẹ̀ sójú ọ̀nà.
24. Angẹli náà tún dúró ní ọ̀nà tóóró láàrin ọgbà àjàrà meji, ògiri sì wà ní ìhà mejeeji.
25. Nígbà tí kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ náà rí i, ó fún ara rẹ̀ mọ́ ògiri, ẹsẹ̀ Balaamu sì fún mọ́ ògiri pẹlu, Balaamu bá tún lù ú.
26. Lẹ́ẹ̀kan sí i, angẹli náà lọ siwaju, ó dúró ní ọ̀nà tóóró kan níbi tí kò sí ààyè rárá láti yà sí.