20. Ẹ mú ọrẹ wá fún OLUWA lára àwọn àkàrà tí ẹ kọ́kọ́ ṣe gẹ́gẹ́ bí ọrẹ láti ibi ìpakà.
21. Lára àwọn àkàrà tí ẹ bá kọ́kọ́ ṣe ni ẹ óo máa mú wá fi ṣe ọrẹ fún OLUWA ní ìrandíran yín.
22. “Ṣugbọn bí ẹ bá kọ̀, tí ẹ kò pa àwọn òfin wọnyi, tí OLUWA fún Mose mọ́,
23. àní àwọn òfin tí OLUWA tipasẹ̀ Mose fún yín, láti ọjọ́ tí OLUWA ti fún un ní òfin títí lọ, ní ìrandíran yín;
24. bí gbogbo ìjọ eniyan Israẹli bá ṣẹ̀, láìmọ̀, wọn óo fi ọ̀dọ́ akọ mààlúù kan rú ẹbọ sísun, olóòórùn dídùn sí OLUWA, pẹlu ẹbọ ohun jíjẹ ati ẹbọ ohun mímu, ati òbúkọ kan fún ẹbọ ìmúkúrò ẹ̀ṣẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ìlànà.
25. Alufaa yóo ṣe ètùtù fún gbogbo ìjọ eniyan Israẹli, a óo sì dáríjì wọ́n nítorí pé àṣìṣe ni; wọ́n sì ti mú ẹbọ sísun ati ẹbọ ìmúkúrò ẹ̀ṣẹ̀ wá fún OLUWA nítorí àṣìṣe wọn.
26. A óo dáríjì gbogbo ìjọ eniyan Israẹli ati àwọn àjèjì tí ń gbé ààrin wọn nítorí pé gbogbo wọn ni ó lọ́wọ́ sí àṣìṣe náà.
27. “Bí ẹnikẹ́ni bá ṣẹ̀ láìmọ̀, yóo fi abo ewúrẹ́ ọlọ́dún kan rú ẹbọ ìmúkúrò ẹ̀ṣẹ̀.
28. Alufaa yóo ṣe ètùtù niwaju pẹpẹ fún olúwarẹ̀ tí ó ṣe àṣìṣe, a óo sì dáríjì í.
29. Òfin kan náà ni ó wà fún gbogbo àwọn tí o bá ṣẹ̀ láìmọ̀, ìbáà ṣe ọmọ Israẹli tabi àjèjì tí ń gbé láàrin ilẹ̀ Israẹli.
30. “Ṣugbọn ẹnikẹ́ni tí ó bá mọ̀ọ́nmọ̀ ṣẹ̀, kò náání OLUWA, ìbáà ṣe ọmọ Israẹli tabi àjèjì tí ń gbé láàrin wọn, a óo yọ olúwarẹ̀ kúrò láàrin àwọn eniyan rẹ̀;
31. nítorí pé ó pẹ̀gàn ọ̀rọ̀ OLUWA, kò sì pa òfin rẹ̀ mọ́, a óo yọ ọ́ kúrò patapata, ẹ̀bi ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀ yóo sì wà lórí rẹ̀.”