21. Ẹni tí ó bá fi Tẹmpili búra, ohun tí ó wà ninu rẹ̀ ati Ọlọrun tí ó ń gbé inú rẹ̀ ni ó fi búra pẹlu.
22. Ẹni tí ó bá fi ọ̀run búra, ó fi ìtẹ́ Ọlọrun ati Ọlọrun tí ó jókòó lórí ìtẹ́ náà búra pẹlu.
23. “Ẹ gbé! Ẹ̀yin amòfin ati ẹ̀yin Farisi, ẹ̀yin aláṣehàn wọnyi! Ẹ̀ ń san ìdámẹ́wàá àwọn èròjà ọbẹ̀ tí wọ́n jẹ́ eléwé, nígbà tí ẹ gbàgbé àwọn ohun tí ó ṣe pataki ninu òfin: bíi ìdájọ́ òdodo, àánú, ati igbagbọ. Àwọn ohun tí ẹ̀ bá mójútó nìyí, láì gbàgbé ìdámẹ́wàá.
24. Ẹ̀yin afọ́jú tí ń fọ̀nà han eniyan! Ẹ̀ ń yọ kòkòrò tín-tìn-tín kúrò ninu ohun tí ẹ̀ ń mu, ṣugbọn ẹ̀ ń gbé ràkúnmí mì mọ́ omi yín!
25. “Ẹ gbé! Ẹ̀yin amòfin ati ẹ̀yin Farisi, ẹ̀yin aláṣehàn. Ẹ̀ ń fọ òde ife ati òde àwo oúnjẹ nígbà tí inú wọn kún fún àwọn ohun tí ẹ fi ìwà olè ati ìwà ìmọ-tara-ẹni-nìkan já gbà.
26. Ìwọ afọ́jú Farisi! Kọ́kọ́ fọ inú ife ná, òde rẹ̀ náà yóo sì mọ́.
27. “Ẹ gbé! Ẹ̀yin amòfin ati ẹ̀yin Farisi, ẹ̀yin aláṣehàn wọnyi. Ẹ dàbí àwọn ibojì tí a kùn ní funfun, tí ó dùn-ún wò lóde, ṣugbọn inú wọn kún fún egungun òkú ati oríṣìíríṣìí ohun ẹ̀gbin.
28. Bẹ́ẹ̀ gan-an ni ẹ̀yin náà rí lóde, lójú àwọn eniyan ẹ dàbí ẹni rere, ṣugbọn ẹ kún fún àṣehàn ati ìwà burúkú.
29. “Ẹ gbé! Ẹ̀yin amòfin ati ẹ̀yin Farisi, ẹ̀yin aláṣehàn wọnyi. Ẹ̀ ń ṣe ibojì fún àwọn wolii, ẹ sì ń ṣe ibojì àwọn eniyan rere lọ́ṣọ̀ọ́.
30. Ẹ wá ń sọ pé, ‘Bí ó bá jẹ́ pé a wà ní ìgbà àwọn baba wa, àwa kò bá tí lọ́wọ́ ninu ikú àwọn wolii.’
31. Nípa gbolohun yìí, ẹ̀ ń jẹ́rìí sí ara yín pé ọmọ àwọn tí ó pa àwọn wolii ni yín.
32. Bó bá rí bẹ́ẹ̀, ẹ̀yin náà ẹ múra, kí ẹ parí ohun tí àwọn baba yín ṣe kù!
33. Ẹ̀yin ejò, ìran paramọ́lẹ̀! Báwo ni ẹ kò ti ṣe ní gba ìdájọ́ ọ̀run àpáàdì?
34. Nítorí èyí ni mo fi rán àwọn wolii, àwọn ọ̀jọ̀gbọ́n ati àwọn amòfin si yín. Ẹ óo pa òmíràn ninu wọn, ẹ óo sì kan òmíràn mọ́ agbelebu. Ẹ óo na àwọn mìíràn ninu wọn ní ilé ìpàdé yín, ẹ óo sì máa lépa wọn láti ìlú dé ìlú.
35. Ẹ óo ṣe gbogbo nǹkan wọnyi kí ẹ lè fi orí gba ẹ̀bi ikú gbogbo eniyan rere tí ẹ ti ta ẹ̀jẹ̀ wọn sílẹ̀; ohun tí ó ṣẹ̀ láti orí Abeli, ẹni rere títí fi dé orí Sakaraya, ọmọ Berekaya, tí ẹ pa láàrin àgọ́ mímọ́ ati pẹpẹ ìrúbọ.
36. Mo fẹ́ kí ẹ mọ̀ dájúdájú pé ìran yìí ni yóo fi orí fá gbogbo ẹ̀bi yìí.
37. “Jerusalẹmu! Jerusalẹmu! Ìwọ tí ò ń pa àwọn wolii, tí ò ń sọ àwọn tí a rán sí ọ ní òkúta pa! Ìgbà mélòó ni mo ti fẹ́ kó àwọn ọmọ rẹ jọ, bí adìẹ tí ń kó àwọn ọmọ rẹ̀ sí abẹ́! Ṣugbọn o kọ̀ fún mi.
38. Wò ó, a óo sọ Tẹmpili rẹ di ahoro.
39. Nítorí náà, mo sọ fun yín pé ẹ kò ní fojú kàn mí mọ́ títí di àkókò tí ẹ óo wí pé, ‘Olùbùkún ni ẹni tí ń bọ̀ wá ní orúkọ Oluwa!’ ”