7. Wọ́n fa kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ náà ati ọmọ rẹ̀ wá, wọ́n tẹ́ aṣọ lé wọn lórí, Jesu bá mú kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ gùn.
8. Ọ̀pọ̀ ninu àwọn eniyan tẹ́ aṣọ wọn sọ́nà; àwọn mìíràn ya ẹ̀ka igi, wọ́n tẹ́ wọn sọ́nà.
9. Àwọn èrò tí ń lọ níwájú, ati àwọn tí wọn ń bọ̀ lẹ́yìn wá ń kígbe pé,“Hosana fún Ọmọ Dafidi,olùbùkún ni ẹni tí ó wá lórúkọ Oluwa.Ògo ni fún Ọlọrun lókè ọ̀run.”
10. Nígbà tí Jesu wọ Jerusalẹmu, gbogbo ìlú mì tìtì. Àwọn ará ìlú ń bèèrè pé, “Ta nìyí?”
11. Àwọn èrò tí ń bọ̀ wá sì dá wọn lóhùn pé, “Jesu, wolii, láti ìlú Nasarẹti ti Galili ni.”
12. Jesu bá wọ inú Tẹmpili lọ, ó lé gbogbo àwọn tí wọn ń tà, tí wọn ń rà kúrò níbẹ̀. Ó ti tabili àwọn tí wọn ń ṣe pàṣípààrọ̀ owó ṣubú. Ó da ìsọ̀ àwọn tí wọn ń ta ẹyẹlé rú.
13. Ó sọ fún wọn pé, “Ó wà ní àkọsílẹ̀ pé, ‘Ilé adura ni ilé mi jẹ́,’ ṣugbọn ẹ̀yin ti sọ ọ́ di ibi tí àwọn ọlọ́ṣà ń sápamọ́ sí.”
14. Àwọn afọ́jú ati àwọn arọ bá wá sọ́dọ̀ rẹ̀ ninu Tẹmpili, ó sì wò wọ́n sàn.