Matiu 20:29-34 BIBELI MIMỌ (BM)

29. Bí Jesu ati àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ ti ń jáde kúrò ní Jẹriko, ọ̀pọ̀ eniyan tẹ̀lé e.

30. Àwọn afọ́jú meji kan jókòó lẹ́bàá ọ̀nà. Nígbà tí wọ́n gbọ́ pé Jesu ń kọjá lọ, wọ́n kígbe pé, “Ọmọ Dafidi, ṣàánú wa.”

31. Ṣugbọn àwọn eniyan bá wọn wí pé kí wọ́n panu mọ́. Ṣugbọn ńṣe ni wọ́n túbọ̀ ń kígbe pé, “Oluwa ṣàánú wa, ọmọ Dafidi.”

32. Jesu bá dúró, ó pè wọ́n, ó ní, “Kí ni ẹ fẹ́ kí n ṣe fun yín?”

33. Wọ́n dá a lóhùn pé, “Oluwa, a fẹ́ kí ojú wa là ni.”

34. Àánú wọn ṣe Jesu, ó bá fi ọwọ́ kàn wọ́n lójú. Wọ́n ríran lẹsẹkẹsẹ, wọ́n bá ń tẹ̀lé e.

Matiu 20