19. Ó bá pàṣẹ pé kí àwọn eniyan jókòó lórí koríko. Ó mú burẹdi marun-un náà ati ẹja meji; ó gbé ojú sókè ọ̀run, ó dúpẹ́, ó bá bù wọ́n, ó kó wọn fún àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀. Àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ bá pín in fún àwọn eniyan.
20. Gbogbo wọn jẹ, wọ́n yó, àjẹkù sì kún apẹ̀rẹ̀ mejila.
21. Àwọn eniyan tí ó jẹun tó ẹgbẹẹdọgbọn (5,000) ọkunrin láì ka àwọn obinrin ati àwọn ọmọde.
22. Lẹsẹkẹsẹ, ó bẹ àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ pé kí wọn wọ ọkọ̀ ojú omi ṣáájú òun lọ sí òdìkejì, nígbà tí ó ń tú àwọn eniyan ká.
23. Nígbà tí ó tú wọn ká tán, ó gun orí òkè lọ gbadura, òun nìkan. Nígbà tí alẹ́ lẹ́, òun nìkan ni ó wà níbẹ̀.
24. Ọkọ̀ ti kúrò ní èbúté, ó ti bọ́ sí agbami. Ìgbì omi wá ń dààmú ọkọ̀, nítorí afẹ́fẹ́ ṣọwọ́ òdì sí wọn.
25. Nígbà tí ó di nǹkan bí agogo mẹta òru, Jesu ń bọ̀ lọ́dọ̀ wọn, ó ń rìn lójú omi òkun.
26. Nígbà tí àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rí i tí ó ń rìn lójú omi, ẹ̀rù bà wọ́n gan-an, wọ́n ń sọ pé, “Iwin ni!” Wọ́n bá kígbe, nítorí ẹ̀rù bà wọ́n.
27. Lẹsẹkẹsẹ Jesu sọ fún wọn pé, “Ẹ ṣe ara gírí. Èmi ni. Ẹ má bẹ̀rù!”