1. Ní ọjọ́ kan náà, Jesu jáde kúrò nílé, ó lọ jókòó létí òkun.
2. Ọ̀pọ̀ eniyan péjọ sọ́dọ̀ rẹ̀ tóbẹ́ẹ̀ tí ó fi wọ inú ọkọ̀ ojú omi kan. Ó jókòó níbẹ̀, àwọn eniyan bá dúró ní etí òkun.
3. Ó sọ ọpọlọpọ ọ̀rọ̀ fún wọn pẹlu òwe. Ó ní: “Ní ọjọ́ kan, afunrugbin kan jáde lọ láti fúnrúgbìn.
4. Bí ó ti ń fúnrúgbìn, àwọn irúgbìn kan bọ́ sẹ́bàá ọ̀nà. Àwọn ẹyẹ bá wá ṣà á jẹ.
5. Àwọn irúgbìn mìíràn bọ́ sórí ilẹ̀ olókùúta tí kò ní erùpẹ̀ pupọ. Lọ́gán ó yọ sókè, nítorí kò ní erùpẹ̀ tí ó jinlẹ̀.
6. Ṣugbọn nígbà tí oòrùn mú, ó jó o pa, nítorí kò ní gbòǹgbò tí ó jinlẹ̀; ó bá rọ.
7. Àwọn irúgbìn mìíràn bọ́ sáàrin igi ẹlẹ́gùn-ún. Nígbà tí wọ́n yọ, ẹ̀gún fún wọn pa.
8. Ṣugbọn àwọn irúgbìn mìíràn bọ́ sórí ilẹ̀ rere, wọ́n sì ń so èso, àwọn mìíràn ń so ọgọọgọrun-un, àwọn mìíràn ọgọọgọta, àwọn mìíràn, ọgbọọgbọn.
9. “Ẹni tí ó bá ní etí láti fi gbọ́ràn, kí ó gbọ́!”
10. Àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ wá sọ́dọ̀ rẹ̀, wọ́n bi í pé, “Kí ló dé tí o fi ń fi òwe bá àwọn eniyan sọ̀rọ̀?”
11. Ó bá dá wọn lóhùn pé, “Ẹ̀yin ni a fi àṣírí ìmọ̀ ìjọba ọ̀run hàn, a kò fihan àwọn yòókù wọnyi.
12. Nítorí ẹni tí ó bá ní nǹkan, òun ni a óo tún fún sí i, kí ó lè ní ànító ati àníṣẹ́kù. Ẹni tí kò bá sì ní, a óo gba ìwọ̀nba díẹ̀ tí ó ní lọ́wọ́ rẹ̀.